Uncategorized

OOGUN EYONU ATURAWO GIDI.

Arakunrin kan wa si odo mi , mo se ayewo kadara re , mo wa ri wipe o ti ba obinrin kan ni ajosepo ri ti obinrin naa si ti gba kadara re. Lati igba ti arakunrin yi ti se asise yi , oogun ko je lara re mo , won da duro lenu ise , bizness ti o tun se pare laipe ojo, gbogbo awon nkan ajalu bere sii sele si .

Mo wa woo wipe kini mo lee fi tuu arakunrin yi sile ninu igbekun ti o wa yi….mo wa se ipeese kan fun pelu Oogun aturawo kadara.

Nigba ti o loo oogun yi , oogun bere si je fun pada , o ri ise miran ti o dara ju ti tele lo. Koda won ti ran nilu oyinbo bayi lati lo se training .
Eyin eniyan mi , e je kin fi oogun yi sile fun ogoro eniyan ti iru nkan bayi nda laamu .

Gbogbo eyin ti e nso wipe oogun kii je lara yin mo tabi eni ti won ti gba ogo re , tabi eniyan ti nkan ti tan fun, ti o si fe lowo pada. O tun sise fun gbogbo eniyan ti kadara re ba le , ti kii ri owo nla gba , gbogbo eniyan ti o ba loo ogun yi , yio pada di eni nla ninu aye .

o ya , ona abayo ti de bayi , o damiloju wipe ti e ba se oogun yi , eo dupe fun eledumare !

   EYONU ATURAWO

Eye kannakan tonifun kan, eye agbe to nifun kan, eye owiwi to nifun kan, ikode mewa, afara oyin, odindi atare kan, ape ijoogun tuntun, ado ide nla kan.
SISE RE
Ao ko awon eroja yen sinu ape , ao gbe sori ina , ao jo papo , ao lo kuna daada lori olo ako okuta ti koni kanle.
Ao wa naa fele fele sori olo naa , ao te ni ifa ejiogbe, ao pe offo re si , ao wa ro etu yi sinu ado ide naa , ao fi igbin nla kan bo , ao ro omi igbin yi si oogun yi ninu ado naa , ao de ado na pada, Ao gbe si aaye owo. Ko gbudo kanle mo lailai .

       GBOLOHUN RE

Ha ha ha, wonni obaje oo, ifa dake roro, bi eniti o ro, wonni obaje ooo, mo rohun selu, wonni obaje ooo, atumoba ni mope oloore, mope atunlero, orunmila ni koiti baje, wonni baba oju ni kannakana fi nmu eji, kannakana Koma foju ohun mu eji mo, orunmila ni koiti baje, won ni baba se e mo wipe oju ni owiwi fi nmu ogede agbagba tii fi laa, owiwi Koma foju oun mu ogede agbagba laa mo, orunmila ni koiti baje, orunmila ni nigbati e sope obaje, nje eyin mo oye ojo ti igbin fi gun oke barun barun?

Won ni awon ko mo, orunnmila wipe odun merindinlogun, osu merindinlogun, ose merindinlogun, ojo merindinlogun, wakati merindinlogun, iseju merindinlogun ni igbin fi gun oke barun barun, nje eyin ri ki eye gbe igbin ri ?

Won ni eewo, Eye kii gbe igbin . Orunmila ni koiti baje, orunmila bi won lere wipe nje eyin mo igba ti igbin fi sokale oke barun barun ? Won ni awon ko mo, orunmila ni oye odun, osu, ose, ojo wakati ati iseju kanna nigbin fi sokale oke barun barun.

Orunmila ni nje egbo wipe eranko nsode igbin lati pa je ? Won ni eewo kamari : odoni yebeyebe ntiko odidere, ojo koni ro ko pa ina iko idi odidere. Tomode, tagba, tokunrin, tobinrin, osho ati aje ki e ma pa Ina Ola temi L O L, nitori ikode kii bo si omi ko ma lee tente, ki irawo emi lagbaja bere sini tan lati oni lo.
Ao se adura si daada , ao ro sinu ado .

    LILO RE

Ti o ba ti di eyin ojo meta ti a ti se oogun yi tan , ao bere sii loo. Ao ma fi Oyin laa . Ao si ma pe gbolohun re si ara ado ide leyin ojo meje meje !
NOTE …Gbogbo irawo ni o lee lo oogun yi , bee si ni gbogbo irawo ni yio ma tunse !

Hmmm, oogun aye atijo to pamo daada ni oogun yi , bee si ni ko po nita .

Iwo ti o ba fe ki oogun yi je fun e , adura ni ki e se fun mi ki aanu olorun ma fi mi sile lailai !

President (OAA, 001)
Ogbon Awon Agba worldwide
08064218196
08157813910

Similar Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published.