Uncategorized

OOGUN EBE ÀGBÀ TODAJU

Ọgbọn awọn agbà ……
Ẹku ojumọ oo eyin eniyan mi , a ku ọjọ mẹta , Elédùà koni fiwa silẹ ooo
Ọlọgbọn lòó dori ẹja mú , awọn iran òmùgò won aa dimu ni irú . Ọlọgbọn ati òmùgọ kosi nínú ipò kanna rara , enikan yíò rise ju ẹnikan lọ nínú ayé. 

Eyin ọjọgbọn , púpọ ninu ìdààmú ati airise ti ọ nba ẹlòmíràn jaa , afowofa rẹ ní. Lóòtó , Elédùà ti sọ awọn agbà lenu latara agbara í ọlọrun fún wọn ṣugbọn nígbà mìíràn aa ma nwa ija awọn agbà.
Gbogbo ẹni toba ti ntù ẹran ti awọn agba soo mọlẹ dandan ni ki ọ ri ojú pipan won. Ẹlòmíràn a ba obìnrin se adehun fifẹ , laimo wipe alágbára ni irufẹ obìnrin bẹ , ti koba mu àdéhùn rẹ ṣe, yíò wá máa rí ìdààmú lonakona.
Ẹyin eniyan mi , gbogbo ẹni toba mo ìjàà jaa , dandan ni ki ọ mọ ebe bẹ óò.  
O ya , mo fẹ fún yín ní oogun ẹbe kan todaju , ti ko jami kule rí. Mo fẹ ki é ṣe kí é fún mi labo .
   OOGUN ẸBE AWON AGBÀ TI ONA ENIYAN FI NLA Abo adie dudu 1, epo obo to gboo daada , ata ijosi 16 tabi jubẹlọ , atare odindi kàn , isasun nla tuntun , ọsẹ dúdú .
      ṢÍṢE RẸAo lọ èpo obo lọtọ, ata ijosi lọtọ, ao wa poo mo ọsẹ dúdú, ao koo sibi kan.
Ao fi atare sí abiya adiẹ sí abiya osi adiẹ náà, ao kaa ori rẹ sí abiya ọtún, ao kaa ẹsẹ rẹ mejeeji mo lára, ao wa gbe sinu isasun yen, ao fi ọsẹ ti a gun nkan mo yen boo mole laaye  ti koni hàn mọ, ao fi ideri rẹ dee pàá mobe. Ao wa gbe sinu asunhan aṣọ funfun , ao lọ ri mọle fún ọjọ méje gbáko.
Ni ọjọ keje yi , ao lọ huu isasun yi jade , ao wa sí ideri isasun yi, ao koo ọsẹ kuro lori adiẹ yen. Ao wa Gun adiẹ yeni kùnà dàada, ao po mo ọsẹ tuntun míràn , ao Gun kùnà gidi, ao ṣẹṣẹ wa poo papọ mo ọsẹ ti a kòó kuro lori rẹ. Ao wa kòó ọsẹ yi sinu isasun yen pada , ao gbèè sí ààyè ọwọ.
        LILO REAo ma wẹ ọsẹ yi ni alé pátá pátá ti a ba fẹ sun. Ao gbudọ jade mọ. Ọ daju tààrà.

Hmm….eyin ènìyàn mi , oogun ẹbe itusile gidi ni mo fún yín lóni , é lo gbìyànjú rẹ ki é mo wipe Elédùà sí ngbo adura olododo ! 
Oríṣi nkan ni oogun yi nṣiṣẹ fún . Bi àpẹẹrẹ
Ọ nṣiṣẹ asinaỌ nṣiṣẹ atudeỌ nṣiṣẹ ẹbeỌ nwoo àìsàn eniti awon agba nbinu síỌ tun nṣiṣẹ ẹrọ asasi . Koda yíò tun ṣiṣe miran lara rẹ yato sí àwọn nkan ti mo kọ sita yi. Oogun ayé àtijó ni !!

President ( OAA ,001)Ọgbọn awọn agbà WorldwideOlùkọ agbà fún ilé ẹkọ ọgbọn awọn agbàHeadquarters, Adebola plaza.Odo Ado , Ado Èkìtì.0806421819608157813910

Similar Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published.