Uncategorized

IPEESE ASINA TODAJU

Ninu asiri ti o yara gbo bukata ju ni ipeese wa. Ti ona ba di tan yanyan ti ao ri owo mo tabi ti jankariwo nkowa loju tabi ti a nri ijakule lonakona….ipeese akeekakaka ni ki e se…
Kosi nkan ti ipeese yi o le koju ninu alamori eniyan laye…ninu awon ise ti o ma nse niyi..
O nsise asina tara
. O nsise ki a le ri owo
. O nsise ipo dundun
.o nsise ki a yo eniyan kuro lewon
. O nsise akoya
O nsise ki a lee ni promotion nibi ise
O nsise iferan tabi isopo ife laarin okunrin ati obinrin.
O nsise ki eniyan o ri contract gba
Kosi nkan ti a doju re ko ti ko ni see

………IPEESE AKEEKAKAKA TODAJU……..
Eran malu ekiri kan ti o tobi die, awo ipeese tuntun, iyere osun, obi ifin alawe merin. Opon ifa tabi paper funfun.
Sise re…..ao da iyereosun yen sori opon ifa tabi inu paper funfun, ao te ni odu osa meji. Ao fi obi yi si iwaju iyereosun ti o te lodu yi ninu opon ifa. Ao wa pe offore si….
Ti a ba ti pee si tan, ao wa da sori eran malu yi ninu awo ipeese.ao wa da ogeere epo pupa lee lori. Ao pa obi yi, ao fi beere ibi ti ao gbe ipeese yi lo ti won o fi gba lowo wa. Ao gbe losi ibe ni ago mewa ale tabi mokanla. Ti o ba di aro ojo keji ni idaji kutu, ao lo gbe awo wa pada…
OFORE:Ake kakaka wolu 3, Abirin kakaka wolu3× A gbe ori iroko ke kakaka 3, Ibiti edarisi ni edari si 3, ibiti e pin jeki si lepin jeki 3, Eyin ni igba Erin ri tiwon nfi eyin lu eyin omo opere opere 3, Eyin ni igba efon ri tiwon nfiiwo lu Iwo omo ogbangandanran ogbangandanran 3, Eyin naa ni igba olopere ri tiwon fi iye nfo janpe janpe kalu 3*, Ewa ni kinni igba Erin ri tiwon fi nfi eyin lu eyin omo opere opere, Eni kinni igba efon ri tiwon fi nfiwo luwo omo ogbangandanran, Ewa ni kinni igba olopere ri tiwon fi iye fo janpe janpe kalu Ero!ero!! Ero!!! Seese lodifa fun koowe ajedo eniyan mabi, Aje oronro masinto, Eewo ni aje ko gbodo pa omo koowe, je ki aje mapa emi(L/L)ooo Kiwon lo Lana rere gbogbo owo nlanla fun mi lati oni lo nio. Nitoripe agbadikaka loruko tanpe ifa orunmila, ninu gbogbo eye to nfo radiradi loju orun, eyin iyami osoronga ati okanlerugba irunmole, loba olodumare pinhun lode orun. Won ni ki olodumare fowo mu ode orun ko yonda ile aye fun awon, olodumare fowo mu ode orun osi yonda ile aye fun yin. Nigbati e dele aye tan, eyin iyami osoronga tunwa ba orunmila pinhun wipe ki orunmila fowo mu aaro ati osan Awon ni awon ni oru. won niti orunmila bati pese fun awon loru, awon yoo mase gbogbo nkan toba fe fun laro ati losan. orunmila wa biwon lere wipe kinni ohun ipese naa ? won niki orunmila mafi eran abeje malu ekiri kan pelu iyereosun pese fun awon. toba ti pe oruko awon awon yo mase gbogbo ohun tobafe fun. Ipese ti eniki orunmila se lojo kinni anaa, ni emi L omo L se fun yin loni yio. Ti o base wipe lododo ati lotito leba nbe lode isalu aye yi, ki e wa lo pese gbogbo ohun ti mo bere funmi ni kiakia bayi o. ao wa se adura pelu aniyan wa. Odaju oo

Similar Posts

Leave a Reply

Your email address will not be published.